Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí/Àgbéyẹ̀wò àwọn ìlànà Ìgbófìnró àkọ́kọ́
Enforcement draft guidelines abstract
In this table, you can find an abstract of the full Enforcement draft guidelines review document. It was created to ensure that every member of the community can understand the new guidelines.
WHO will be responsible for enforcing the UCOC?
- The WMF, designated people such as code enforcement officers, and a new committee called the Universal Code of Conduct Coordinating Committee (AKA the U4C).
- The U4C will oversee the process of UCoC enforcement, manage special cases, provide guidance and training, and monitor enforcement of the UCoC.
- Local and global functionaries[1] will have guidance to know how to enforce the UCoC even if they are not part of the U4C.
HOW will this be done?
- The UCoC should be visible in as many places as possible.
- Certain individuals will have to declare their respect for and adherence to the UCoC.
- Local communities, affiliates, and the WMF should develop and conduct training for community members so they can better address harassment and other UCoC violations.
- The guidelines also lay out recommendations for which parties should address what types of UCoC violations.
- The guidelines suggest certain principles for processing and filing cases to ensure UCoC violations are addressed similarly across all projects.
WHAT else needs to be done to enforce the UCOC?
- The draft recommends the creation of a common, centralized reporting system.
- The draft also recommends expanding the coverage of ArbComs to increase global coverage.
- The draft notes that appeals should be possible and practically available to individuals who were sanctioned for UCoC violations.
HOW can I get involved in the EDGR process?
- The Drafting Committee has provided questions for the community to think about in regards to this draft. Please answer a couple of them in your preferred discussion venue.
Introduction
Ìgbìmọ̀ fún Kíkọ ti Ipele Ìkejì Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí npè fún àwọn èrò lórí àwọn ìlànà ìgbófìnró àkọ́kọ́ ti Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí (UCoC). Àsìkò fún ìgbèròsílẹ̀ yìí ó wáyé láti 17 August 2021 títí dé 17 October 2021. À npè fún ìdásí yin lórí ojú-ewé ọ̀rọ̀ ìlànà, àwọn ojú-ewé ọ̀rọ̀ ìtúmọ̀, àwọn ìjíròrò ìbílẹ̀, àwọn ìpàdé ìjíròrò, àwọn ìjíròrò ayélujára, orí àwọn pẹpẹ mìíràn, àti ìwé sí ucocprojectwikimedia.org, ní àwọn èdè tó bá wù yín.
Ati ṣe àkójọ àwọn èrò lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará Wikimedia lákòkò iṣẹ́-àkànṣe UCoC yìí. Àwọn ìgbìmọ̀ fún kíkọ tó ní àwọn olùfarajìn mọ́kànlá àti àwọn òṣìṣẹ́ Wikimedia Foundation mẹ́rin, ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn èrò wọ̀nyí. Wọ́n jùmọ̀pọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù láti kọ àwọn ìlànà òfin ìgbófìnró, fún àtúnyẹ̀wò ìjìnlẹ̀ àwọn ará Wikimedia. A ó lo àwọn èrò tí abá gbàkalẹ̀ láti ṣe àtúnṣe síbẹ̀ sí àwọn ìlànà náà.
O lè yan èdè tí ó bá wù ọ́ àti ọ̀nà tí o fẹ́ gbà kópa. A ó ṣètò àwọn ìjíròrò lórí ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia, ní oríṣiríṣi èdè. A nílò àwọn olùfarajìn láti báwa ṣètò àwọn ìjíròrò lórí àwọn iṣẹ́-àkànṣe ti wọn. Àwọn olùṣètò ntèlé àwọn oríṣiríṣi pẹpẹ yìí, wọ́n sì wà nlẹ̀ láti dáhùn àwọn ìbéèrè, àti láti ṣètò àwọn ìjíròrò.
A ó ṣe àkópọ̀ àwọn ìjíròrò, a ó sì gbéwọn kalẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ fún Kíkọ ní ọ̀sẹ̀ méjì-méjì. A ó ṣàtẹ̀jáde àwọn àkópọ̀ yìí lórí ojú-ewé yìí.
Àwọn ìlànà Ìgbófìnró àkọ́kọ́
Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlànà ìgbófìnró tí Ìgbìmọ̀ fún Kíkọ ti Ipele Ìkejì Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí kọ. O lè dásí ètò yìí ní ojú-ewé ọ̀rọ̀ àti lórí àwọn ìjíròrò ìbílẹ̀. Jọ̀wọ́ máṣe sàtúnṣe ojú-ewé yìí. A ó ṣe àtúnṣe lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò ìjìnlẹ̀ àwọn ará Wikipedia ní oríṣiríṣi èdè. Ìgbìmọ̀ fún Kíkọ yí ó ṣe àwọn àtúnṣe sí ìlànà yìí lẹ́yìn àkókò àgbéyẹ̀wò yìí. |
Àkíyèsi lát'ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ fún Kíkọ
Jọ̀wọ́ fi s'ọ́kàn pé Àwọn Ìlànà Àkọ́kọ́ Ìgbófìnró UCoC tí a pèsè nínú ojú-ewé yìí ṣe yípadà, a ó sì ma ṣe àgbéyẹ̀wò rẹẹ̀ ní lemọ́lemọ́ pẹ̀lú èrò lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará Wikimedia, àti Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí. Ìgbìmọ̀ ti pèsè àwọn ìbéèrè fún àwọn ará láti gbèrò lórí ìlànà yìí.
Àkótán
Ìtúmọ̀ Ètò Ìgbófinró
Ètò Ìgbófìnró ni ìdènà, ìṣàwàrí, ìwádìí, àti ìgbófìnró àwọn ìwà tí ó tako Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí. Ètò Ìgbófìnró jẹ́ ojúṣe àwọn àlákoso, Ìgbìmọ̀ elétò Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí ["Ìgbìmọ̀ U4C" - Orúkọ yìí lè yípadà], àti Wikimedia Foundation. A gbọdọ̀ ṣeléyí ní pípé, kánkán, àti ní dédé káàkiri Àjọṣepọ̀ Wikimedia. Nítorínáà, àwọn ènìyàn tí a fi lé lọ́wọ́ láti gbé òfin Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí ró, wọ́n gbọdọ̀ mọ òfin náà dójú ìwọ̀n.
Ìgbófìnró UCoC yí ò wáyé nípa iṣẹ́ ìdènà àti ìpolongo, ṣíṣe àwọn ìkìlọ̀ láti pàrọwà fún àwọn ènìyàn tó ní ìwà àìbójúmu láti tèlé òfin, atún lè fi ìjìyà tó tọ́ jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀, tàbí àwọn ìgbésẹ̀ míràn tí ó yẹ. Àwọn alákóso kárí-ayé àti ìbílẹ́ tó ngbé àwọn òfin àti ìlànà ró lórí àwọn iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia gbọdọ̀ ní ìmọ̀ lórí ètò àti ìlànà ìgbófìnró yìí.
Ìtúmọ̀ Òṣìṣẹ́ Ètò Ìgbófìnró:
[Osise Eto Igbofinro - Òrúkọ yìí lè yípadà] jẹ́ olùfarajìn tàbí òṣìṣẹ́ Àjọṣepọ̀ Wikimedia tí ó ní àwọn ìmọ̀ àti àwọn ohun-èlò, tí ojúṣe rẹ̀ sì jẹ́ dídènà, ṣíṣàwárí, ṣíṣe ìwádìí àti gbígbé òfin Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí ró.
Ìtúmọ̀ Ìgbìmọ̀ Ètò Ìgbófìnró - "Ìgbìmọ̀ U4C":
Ìgbìmọ̀ fún Kíkọ dábà ṣíṣẹ̀dá ìgbìmọ̀ ayérayé tí ojúṣe rẹ̀ẹ̀ yí ò jẹ́ láti ṣàbojútó UCoC, pẹ̀lúpẹ̀lú jíjẹ́ alábàṣepọ̀ ìgbófìnró UCoC pẹ̀lú àwọn ará Wikimedia àti Wikimedia Foundation.
"Ìgbìmọ̀ U4C" yí ò ṣàbójútó àwọn rírú òfin UCoC, wọ́n lè kópa nínú àwọn ìwádìí síbẹ̀, wọn yíò sì dábà ìgbésẹ̀ níbi tí ó bá tiyẹ.
Níbi tí ọ̀rọ̀ bá ti tabá àwọn agbófìnró tábì tí ó lè ṣe okùnfà ẹjọ́ fún Wikimedia Foundation tàbí oníṣe, "Ìgbìmọ̀ U4C" lè tọrọ ìrànlọ́wọ́ tàbí ohun-èlò lát'ọ̀dọ̀ Wikimedia Foundation láti yanjú ọ̀rọ̀ náà.
Nígbà tí ó bá pọn dandan, "ìgbìmọ̀ U4C" yí ò ran Wikimedia Foundation lọ́wọ́ nínú ìwádìí ọ̀rọ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lú, "Ìgbìmọ̀ U4C" yíò ṣàbojútó àti àyèwò ètò ìgbófìnró ní ìgbàdéìgbà, wọ́n sìlè mú àwọn àbá lórí àtúnṣe UCoC wá fún àyèwò Wikimedia Foundation àti àwọn ará Wikimedia.
Lẹ́yìn ìdásílẹ̀, ìgbìmọ̀ ayérayé yìí yóò pinnu lórí iye ìgbà tí ó yẹ kí wọ́n pàdé, àti irú àwọn ẹ̀sùn tí wọn yíò dásí. A dábàá pé kí ìgbìmọ̀ yìí dásí irú àwọn èsùn tí a tòjọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n ni ìpinnu lórí èyí:
- Nígbàtí kò bá sí ètò ìbílẹ̀ láti ṣe ìwádìí ẹ̀sùn;
- Nígàbtí àwọn ètò ìbílẹ̀ kò nípọn láti yanjú ọ̀rọ̀;
- Àwọn wàhálà ètò.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ U4C yí ò fọwọ́sí ìwé-àdéhùn "non-disclosure" láti fún wọn láyè láti wo àwọn ọ̀rọ̀ tí kò sí ní gbangba.
Iṣẹ́ ìdènà (àròkọ 1 àti 2 UCOC)
Ìdí fún iṣẹ́ ìdènà ni láti mú kí àwọn oníṣẹ́ lórí àwọn iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia Foundation àti àwọn míràn tí UCOC tabá mọ̀n wípé òfin náà wà, àti pípolongo fún ìgbọràn àtinúwá.
Àwọn Ìmọ̀ràn fún Ìgbóràn Àtinúwá Ìtumọ̀ UCoC:
Irú UCoC ojúlówó wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. A fẹ́ kí ìtúmọ̀ rẹẹ̀ wà fún àwọn èdè tókù tí à nlò lórí àwọn iṣẹ́-àkànṣe Wikimeda. Ní àwọn ìgbà tí àlàyé bá yàtọ̀ síra wọn láàrín àwọn èdè, ti t'ẹ̀dẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni a gbọ́dọ̀ lò.
Àwọn Ìmọ̀ran lórí Ìgbaniláyè UCoC láàrín Àwọn Ará Wikimedia àti Òṣìṣẹ́ Foundation:
UCoC yí ò tabá ẹnikẹ́ni tí ó nṣe àfikún sí àwọn iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia lórí ayélujára tàbí ní ojúkojú. Àwọn ènìyàn tí a ti tòjọ yìí gbọdọ̀ pinnu (nípa títọwọ́ bòwé àdéhùn tàbí ọ̀nà míràn) láti tẹ̀lẹ́ Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí:
- Gbogbo òṣìṣẹ́, ará Ìgbìmọ̀ Onígbọ̀wọ́, àti agbaṣẹ́ṣe Wikimedia Foundation;*Àwọn oníṣẹ́ tó ní àwọn ohun èlò alákòso bíi: syop, bureaucrat, steward, admin, checkuser;
- Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ lo àwọn ohun ìdánimọ̀ Wikimedia Foundation fún àwọn ìpàdé, iṣẹ́-àkànṣe, asojú, ẹgbẹ́ àjọṣepọ̀, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ;
- Ẹnikẹ́ni tí ó nwá iṣẹ́ ẹ̀ka Àjọṣepọ̀ Wikimedia lórí ayélujára tàbí ojúkojú (bí àpẹẹrẹ, ènìyàn tàbí ẹgbẹ́ tó fẹ́ polongo ìpàdé, ìgbìmọ̀, tàbí Ìwádìí tí Wikimedia ti ṣètò);
- Ẹni tó nṣiṣẹ́ Ètò Ìgbófìnró
Àwọn Ìmọ̀ràn lórí È̩kọ́ UCoC láàrín àwọn Ará WIkimedia:
Àwọn ará Wikimedia, Wikimedia Foundation àti ẹ̀ka Wikimedia kó ṣètò ẹ̀kọ́ fún àwọn ará láti lè ṣe ìdánimọ̀, ìbáwí àti ìdẹ́kùn àwọn ìpalára tí Ìyọlẹ́nu nfà. È̩kọ́ fún àwọn oníṣẹ́ yẹ kí óní, àwọn ìlànà àti ohun èlò fún ìdánimọ̀ àwọn ìwà àíbójúmu àti ìlànà lórí ìdáhùn sí irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀.
- È̩kọ́ yí ò ní àwọn ipele ìwé-ẹ̀rí wọ̀nyí[2]:
- Ipele àkọ́kọ́: Àkópọ̀ ìmọ̀ lórí UCoC
- Ipele ìkéjì: Ipá láti dáhùnsí rírú òfin UCoC
- Ipele ìkẹ́tàa: Ipá láti dáhùnsí ẹ̀jọ́ UCoC
- Ipele ìkẹ́rìn: Àtìlẹ́yìn fún àwọn olùfaragba ìyọlẹ́nu ní ọ̀nà tí óyẹ (wo: Ètò Ìdẹ́kùn Ìyọlẹ́nu)
- Ìtọ́kasí sí ojú-ewé UCoC gbọdọ̀ wà lórí:
- Àwọn ojú-ewé ìforúkọsílẹ̀;
- Àwọn ojú-ewé ìfipamọ́ àtúnṣe fún àwọn oníṣẹ́ tí kò wọlé sórí iṣẹ́-àkànṣe pẹ̀lú ìdánimọ̀;
- Ojú-ẹsẹ̀ àwọn iṣẹ́-àkànṣe;
- Ojú-ẹsẹ̀ àwọn ojú-ewé ayélujára àwọn ẹ̀ka Wikimedia;
- Ìfihàn lórí àwọn ìpàdé ojúkojú;
- Àwọn ibò míràn tí ó yẹ
Iṣẹ́ ìdáhùn (àròkọ 3 UCOC)
Ìdí fún iṣẹ́ ìdáhùn ní láti pèsè àwọn ọ̀nà fún gbígbàsílẹ̀ àwọn ẹ̀sùn, pípèsè àwọn ohun-èlò fún ìwádìí àwọn ẹ̀sùn, ìtúmọ̀ àwọn oríṣiríṣi òfin rírú àti ìlànà ìgbófìnró, pẹ̀lú àwọn àba lórí àwọn ohun-èlò ìfẹ̀sùnkàn, àti ọ̀nà fún ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.
Ìpìlẹ̀-òye fún gbígbàsílẹ̀ àti ìwádìí àwọn ẹ̀sùn
- Olùfaragba ìyọlẹ́nu àti ẹni tómọ̀ nípa rẹ̀ ni ó lè fi ẹ̀sùn rírú òfin UCoC kàn;
- A gbọdọ̀ yanjú àwọn èsùn nípasẹ̀ ìdámọ̀ràn dípò ìfìjìyà jíjẹ, níbi tí ó bá ti yẹ;
- Agbọdọ̀ yanjú àwọn ẹ̀sùn ní àkókò tí ó yẹ;
- A lè fi àwọn ẹ̀sùn míràn sípò pàtàkì nígbà tí ó yẹ;
- Agbọdọ̀ ju àwọn ẹ̀sùn tí kò tọ́ dànù;
- Agbọdọ̀ yanjú àwọn ẹ̀sùn tí kò tóhùn kan ní ìlànà ìbílẹ̀ iṣẹ́-àkànṣe;
- Agbọdọ̀ gbé ẹ̀sùn lọ sí òkè níbi tí ó bá ti yẹ;
- Irú ìyà tí a lè fi jẹ ẹni tó rú òfin UCOc yí ò dá lórí irú ojúṣe wọn (òṣìṣẹ́ tó ngbowó, oníṣẹ́ tí a dìbò fún tàbí yàn, olùfarajìn, etc.), bí wọ́n ti rú òfin náà, àti bí rírú náà ti ga tó;
- Àyè yí ó wà fún ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, ní ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ tí yíó yàtọ̀ sí èyí tó dá ẹjọ́ àkọ́kọ́.
Pípèsè àwọn ohun èlò fún ìwádìí àwọn ẹ̀sùn
Agbègbè iṣẹ́ àwọn ArbCom lórí àwọn iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia gbọdọ̀ gbòòrò nípa títèlé àwọn ìmọ̀ràn yìí:
- Ìgbìmọ̀ ArbCom ìṣọ̀kan lát'orí onírúurú iṣẹ́-àkànṣe, ní èdè kan láti ní ìgbìmọ̀ ìgbófìnró tó já fáfá;
- Àwọn iṣẹ́-àkànṣe tí ó tóbi (àwọn ìwọn tí wọ́n ti dá lábàá ni: iye àwọn oníṣẹ́, iye sysops. Ìgbìmọ̀ ni yí ò dámọ̀ràn ìwọ̀n yìí fún iṣẹ́ Wikimedia Foundation pẹ̀lú U4C) yẹ kí wọ́n ní ArbCom tiwọn;
- Rí dajú wípé ArbCom ìṣọ̀kan kò dá lórí Wikipedia nìkan, àwọn iṣẹ́-àkànṣe gbọdọ̀ dọ́gba nípa níní ojú-ewé tí kò gbe iṣẹ́-àkànṣe kankan, fún ìgbìmọ̀ náà;
- Jẹ́ kí onírúurú èdè pín ArbCom náà, tí àtìlẹyìn báti wà fún ìkópa àwọn ará àjọṣepọ̀ náà.
Irú àwọn òfin rírú àti àwọn ìlànà ìgbófìnró
Abala yìí yíò pèsè àtọ̀jọ onírúurú àwọn òfin rírú, pẹ̀lú àwọn ìlànà ìgbófìnró tó wà fún wọn.
- Àwọn òfin rírú tí ó mú ìhàlẹ̀ ìpalára dání:
- È̩ka Trust & Safety ni yíò dáhùn
- Áwọn òfin rírú tí ó la àwọn agbófìnró tàbí ilé-ẹjọ́ ìjọba lọ:
- È̩sùn yìí gbọdọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ka àwọn asòfin Wikimedia Foundation ní kánkán, fún àgbéyẹ̀wò wọn
- Áwọn òfin rírú tó jọmọ́ ètò ìjọba ẹ̀ka Wikimedia:
- AffCom ni yí ò dáhùn
- Ìjákulẹ̀ ètò ìgbọ́ràn sí UCoC:
- "Ìgbìmọ̀ U4C" ni yí ó dáhùn;
- "Ìgbìmọ̀ U4C" yí ó dáhùn sí àwọn òfin UCoC rírú tóbá rékọjá àwọn iṣẹ́-àkànṣe lát'orí àwọn àlákoso
- Àwọn òfin rírú tí kò ṣẹlẹ̀ lórí wiki:
- "Ìgbìmọ̀ U4C" yíò dáhùn, tí àwọn olùdarí ìpàdé tàbí ẹ̀ka náà bá fi ẹ̀sùn yíì kàn
- Àwọn òfin rírú tó ṣẹlẹ̀ lórí wiki:
- Òfin rírú tó rékọjá àwọn iṣẹ́-àkànṣe: "Ìgbìmọ̀ U4C" yíò dáhùn yálà tààrà tàbí tí àwọn alákòso ìbílẹ̀ bá pè wọ́n sí ẹ̀sùn náà[3];
- Àwọn òfin rírú UCoC lórí wiki kan: Àwọn ètò ìjọba ìbílẹ̀ iṣẹ́-àkànṣe kọ̀ọ̀kan ni yí ò dáhùn sí èyí ní ìtèlé ìlànà tí ó wà nlẹ̀
Àwọn Ìmọ̀ràn fún ohun-èlò ìfẹ̀sùnsùn àti ìwádìí
Láti jẹ́ kí ìfẹ̀sùnsùn àti ìwádìí àwọn òfin rírú UCoC túnbọ̀ ṣeéṣe, Wikimedia Foundation yí ó pèsè, yí ó sì ṣètọ́jú ohun èlò tó sọ̀kan fún fífẹ̀sùnsùn àti ṣíṣe ìwádìí lórí MediaWiki. Ohun-elo yìí gbọdọ̀ gba olùfẹ̀sùnsùn láàyè láti pèsè ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òfin UCoC tí oníṣẹ́ tí rú, pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa arawọn àti àwọn ará àjọṣepọ̀ míràn tí ẹ̀sùn yìí tabá.
Àwọn ẹ̀sùn gbọdọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé láti jẹ́ kíí ẹjọ́ ṣeé dá àti láti pèsè àkọsílẹ̀ tó péye nípa ọ̀rọ̀ tó wà nlẹ̀. Lára àwọn àlàyé yìí ni:
- Ọ̀nà tí ìwà tí o fín sùn fi rú òfin Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí;
- Tani àti tani òfin rírú UCoC yìí ṣe ìpalára fún;
- Ọjọ́ àti àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀;
- Àwọn ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀;
- Àwọn àlàyé míràn tó wúlò fún ìgbìmọ̀ ìgbófìnró láti dájọ́ ọ̀rọ̀ náà.
Ohun-èlò yìí gbọdọ̀ ma nṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìlò-ìrọ̀rùn, ààbò fún ìdánimọ̀ àti ìpèsè fún ìwádìí àti ìjábọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gbangba:
- Ààbò fún ìdánimọ̀
- Pèsè ààyè fún ìfẹ̀sùnsùn gbangba (tí àlàyé ọ̀rọ̀ náà yí ó wà fún gbogboògbò), tàbí ní ìkọ̀kọ̀ (bí àpẹẹrẹ, tí àwọn gbogboògbò kò ní mọ ìdánimọ̀ olùfẹsùnsùn; tí gbogboògbò kòní mọ ìdánimọ̀ àwọn ènìyàn tí ẹ̀sùn náà tabá; àti àwọn àpẹẹrẹ bí èyí);
- Ṣàlàyé wípé ìfẹ̀sùnsùn ìkọ̀kọ̀ léè dí àwọn ọ̀nà fún ìyanjú ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ - bí àpẹẹrẹ, ìjíròrò gbangba dípò ìfìyajẹni kò lè ṣeéṣe ní ìfẹ̀sùnsùn ìkọ̀kọ̀;
- Gba àwọn oníṣẹ́ láàyè láti fẹ̀sùnsùn tí wọn kò bá tilẹ̀ wolé sóri wiki pẹ̀lú ìdánimọ̀
- Ètò ìwádìí
- Pèsè fún ètò ìwádìí ìkọ̀kọ̀ fún àwọn ẹ̀sùn tí àwọn ìgbìmọ̀ ìgbófìnró yí ò dáhùn sí;
- Pèsè fún ààyè láti gba àwọn ẹ̀sùn sókè sí àwọn ẹ̀ka tó tọ́;
- Tọ́ka àwọn ọ̀rọ̀ UCoC rírú tó nlọ lọ́wọ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ ti tẹ́lẹ̀ tí ó kan oníṣẹ́ kanáà;
- Pèsè fún ọ̀nà láti so àwọn ìfẹ̀sùnsùn tí kò ṣẹlẹ̀ lórí ayélujára pẹ̀lú ètò ìfẹ̀sùnsùn kan;
- Jẹ́kí àwọn tí ó nṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ ju àwọn ẹ̀sùn tí kò tọ́ nù
- Ìjábọ̀ gbangba
- Pèsè fún ọ̀nà láti ṣ'àpamọ́ gbogbo ẹ̀sùn nígbangba láti ṣàwárí wọn, nígbàtí a sì tún pèsè ààbò ìdánimọ̀ fún àwọn ẹ̀sùn ìkọ̀kọ̀;
- Yan ìdánimọ̀ gbangba fún àwọn ẹ̀sùn kọ̀ọ̀kan fún ìdí ìṣàwàrí gbangba;
- Pèsè fún ìgba àlàyé sílẹ̀ lórí ìlò ohun-èlò yìí, fún ìdí ìjábọ̀ ìgbófìnró UCoC fún gbogboògbò, pẹ̀lú ọ̀wọ̀ fún ìdánimọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀ yìí
Kò pọn dandan fún àwọn ènìyàn tí a fún ní ojúṣe ìgbófìnró UCoC láti lo ohun-èlò yìí, wọ́n sìle tẹ̀síwájú láti lo àwọn ohun-èlò míràn tí wọ́n lérò wípé ó ṣiṣẹ́ náà dáradára, níwọ̀nìgbàtí wọ́n bá nṣe àwọn ìwádìí àti ìjábò ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìlò-ìrọ̀rùn, ààbò fún ìdánimọ̀ àti ìpèsè fún ìwádìí àti ìjábọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gbangba, kanáà.
Àwọn Ìmọ̀ràn fún àwọn ètò ìgbófìnró ìbílẹ̀
Níbi tí o bá ti ṣéeṣe, àn gbàníyànjú wípé kí àwọn ètò ìgbófìnró tó wà nlẹ̀ gbé ojúṣe ìgbàsílẹ̀ àti ìwádìí èsùn UCoC ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tí a ti là kalẹ̀. Láti rí dájú wípé ètò ìgbófìnró wà ní ìdógba káàkiri àjọṣepọ̀, à ngba àwọn alákòso níyànjú láti lo àwọn ìmọ̀ràn tí ati là kalẹ̀ ní ìwọ̀n iṣẹ́-àkànṣe kọ̀ọ̀kan.
- È̩kọ́ àti àtìlẹyìn
- Àwọn ohun-èlò ìtúmọ̀ tí Wikimedia Foundatio yí ó pèsè nígbà tí ìjábọ̀ bá wá ní èdè tí àwọn ìgbìmọ̀ kò mọ̀ dáradára, tí ẹ̀rọ ayélujára kò sì ní pèsè ìtúmọ̀ tó dójúìwọ̀n;
- È̩kọ́ fún àwọn alákòso iṣẹ́-àkànṣe àti òṣìṣẹ́ láti kọ́ ìlànà ìwádìí àti òye UCoC
- Ètò àìlójú ìṣájú
- Àwọn òfin ìdẹ́kùn ojú-ìṣajú tí yí ó ran àwọn alákòso àti àwọn míràn lọ́wọ́ láti séra tàbí yọwọ́ kúrò lórí ìjábọ̀ tí ọ̀rọ̀ náà bá tabá wọn;
- Ní ìdìmú àwọn ètò ìyanjú ọ̀rọ̀ tó wà nlẹ̀, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá dárúkọ nínú ẹ̀sùn gbọdọ̀ yọwọ́ nínú ìwádìí ọ̀rọ̀ náà;
A dábà wípé kí Wikimedia Foundation pèsè ètò tí àwọn oníṣẹ́ yí ò fi lè jẹ́wọ́ tí wọ́n bá rí ààbò nínú iṣẹ́-àkanṣe wọn tàbí tí wọn kò bá rí ààbò.
- Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó péye láàrín àwọn alákòso
- Àwọn ààyè, ìlànà àti ìwúrí fún àwọn alákòso láti jọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn alákòso tókù láti ṣe ìwádìí àti ìdájọ́, ní pàtàkì jùlọ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó takókó (bíí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tabá ènìyàn tópọ̀, tàbí tí ojú-ewé ìtàn rẹẹ̀ jìn)
- Ètò gbangba
- Àwọn ará Wikimedia àti/tàbí Wikimedia Foundation gbọdọ̀ pèsè ìjábọ̀ lórí ipọn àwọn onírúurú ìyọlẹ́nu tó wọ́pọ̀ tí a lè lò láti ṣ'àwọ̀rán àwọn ìdájọ́ oríṣiríṣi. Eléyì yí ó ràn àwọn alákòso tàbí àwọn ìgbìmọ̀ ìgbófìnró míràn lọ́wọ́ láti lo àwọn ìmọ̀ràn yìí láti pinnu lórí ipọn ẹ̀ṣùn
Fún àwọn ìjíròrò lórí Wikimedia tí kò ṣẹlẹ̀ lórí wiki (bíi: Discord, Telegram, etc.), àwọn òfin ìlò Wikimedia kò dè wọ́n. Òfin àwọn pẹpẹ tí ìjíròrò náà ti nṣẹlẹ̀ ló dè wọ́n. Ṣùgbọ́n, a lè gba ìwà àwọn ará Wikimedia lórí àwọn pẹpẹ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí nínú àwọn ẹ̀sùn òfin rírú UCoC. A dábàá pé kí àwọn pẹpẹ tí kò sí lórí wiki pèsè ìlànà tí yí ò dẹ́kùn gbígbé àwọn ìjíròrò orí wiki lọ sórí wọn.
Àwọn Ìmọ̀ràn lórí ìwádìí àwọn ẹjọ́ kòtẹ́milórùn
Àwọn ènìyàn tí ó bá ti rú òfin UCoC gbọdọ̀ le bèrè fún ìdájọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Ìpèníjà yìí lè dá lórí bóyá òfin rírú wáyé tàbí kò wáyé, ọ̀nà tí ìgbìmọ̀ fi ṣe ìwádìí, tàbí irú ìjìyà tí a fi fún ẹni tó rú òfin UCoC. Ìwádìí àti ìdájọ́ kòtẹ́milórùn gbọdọ̀ wá lát'ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ tí kò dásí ètò ìgbófìnró àkọ́kọ́, ìdájọ́ ìgbìmọ̀ náà sì gbọdọ̀ dálórí àwọn èyí:
- Bíí òfin rírú UCoC náà ti ga tó;
- Bíí ẹni ná báti rú òfin UCoC tẹ́lẹ̀ rí;
- Irú ìjìyà tí a fi fún ẹni tó rú òfin UCoC;
- Ìwọ̀n ìpalára tí òfin rírú UCoC fà fún àwọn ènìyàn, ẹgbẹ́ oníṣẹ́, àti iṣẹ́-àkànṣe ní ọ̀kan
Àwọn ìgbìmọ̀ ìgbófìnró ìbílẹ̀ lè dìbò láti ro àwọn ojú-ọ̀rọ̀ míràn, tàbí pàtàkì wọn, nígbàtí wọ́n bá npinnu láti gba ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wolé. Ètò fún iṣẹ́-àkànṣe kọ̀ọ̀kan yí ó dá lórí ìpinnu ti wọn. Ní ìgbà tí ìgbìmọ̀ fún ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kò ní ìmọ̀ èdè tí ìgbìmọ̀ àkọ́kọ́ lò, wọ́n gbọdọ̀ ní àtìlẹyìn ìtúmọ̀ lát'ọ̀dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀.
Wíwo Iwájú
Jọ̀wọ́ fi s'ọ́kàn pé Àwọn Ìlànà Àkọ́kọ́ Ìgbófìnró UCoC tí a pèsè nínú ojú-ewé yìí ṣe yípadà, a ó sì ma ṣe àgbéyẹ̀wò rẹẹ̀ ní lemọ́lemọ́ pẹ̀lú èrò lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará Wikimedia, àti Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí. Ìgbìmọ̀ ti pèsè àwọn ìbéèrè fún àwọn ará láti gbèrò lórí ìlànà yìí.
Ìdánwò àwọn ohun-èlò ìfẹ̀sùnsùn àti "Ìgbìmọ̀ U4C" yí ò wáyé lẹ́yìn ọdún kàn àkọ́kọ́ ìṣípòpadà. Nígbàtí ọdún bá parí, àtúnṣe lè wáyé nípa lílo àwọn àkíyèsí láti tún àwọn ohun èlò ìfẹ̀sùnsùn ṣe, pẹ̀lú àlàyé síbẹ̀ lórí àwọn iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbófìnró.
Ìbéèrè fún àwọn Ará Àjọṣepọ̀
- Ìgbẹ́jọ́ lọ sókè: Ibo ni àwọn ẹ̀sùn yí ó lọ, àwọn ìgbìmọ̀/ẹgbẹ́/adájọ́ wo ní ó yẹ kí ó ṣe ìwádìí wọn.
- Àwọn ìlànà fún ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn (lẹ́yìn tí a bá ti dáhùn ìbéèrè àkọ́kọ́ lórí "ìgbẹ́jọ́ lọ sókè").
- Ṣé kí Ìgbìmọ̀ U4C ṣe ìwádìí ẹ̀sùn kọ̀ọ̀kan tàbí ṣe ìwádìí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn?
- Ìgbà wo ni ó tọ́ kí ènìyàn lè bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ẹjọ́ kòtémilọ́rùn fún rírú òfin UCoC?
- Irú àwọn ìwà àti ẹ̀rí wo ni a fẹ́ gbà wolé kí a tó fọwọ́sí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn?
- Tani kí ó s'ètò ìwádìí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn?
- Iye ìgbà wo ni ènìyàn lè bèèrè ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fún rírú òfin UCoC?
- Dé ipa wo ni kí a gba iṣẹ́-àkànṣe kọ̀ọ̀kan láti pinnu lórí bí wọ́n ṣe fẹ́ gbé òfin UCoC ró?
- Báwo ni kí a ṣe yan àwọn ènìyàn fún ìgbìmọ̀ U4C?
- Àwọn àbáà oníṣẹ́ tí a ní lọ́wọ́ ni: àwọn CheckUsers, oversighter, bureaucrat, alákòso àwọn iṣẹ́-àkànṣe ìbílẹ̀, ará ìgbìmọ̀ arbitration, òṣìṣẹ́ Wikimedia Foundation, ẹ̀ka Wikimedia, etc.)
- Ṣé kí á s'ètò ìgbìmọ̀ adelé nígbàtí a nṣ'ẹ̀dá ìgbìmọ̀ "U4C"lọ́wọ́?
- Ṣé kí á da ìgbìmọ̀ ìhùwàsí àgbáyé, bíi Ìgbìmọ̀ fún "Technical Code of Conduct" pọ̀ mọ́n U4C?