Wikimedia Foundation elections/2021/Candidate Requirements/yo

This page is a translated version of the page Wikimedia Foundation elections/2021/Candidate Requirements and the translation is 100% complete.

The election ended 31 Oṣù Kẹjọ 2021. No more votes will be accepted.
The results were announced on 7 Oṣù Kẹ̀sán 2021. Please consider submitting any feedback regarding the 2021 election on the elections' post analysis page.

Yíyan ọmọ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe ni ó wà ní ìlànà duty of care. Ìlànà yí ni ó bójú mu tí ó sì ní ànfaní tó pọ̀ nínú fún àwọn olùdíje. Ìlànà "Duty of care" yí ni ó nííṣe pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ díje sípò. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ ọmọ ìgbìmọ̀ kò gbọdọ̀ hu ìwà ìdójútì bí ó ti wulẹ̀ kí ó Mọ.

2021 Board Elections
Main Page
Candidates
Voting information
Single Transferable Vote
Results
Discussions
FAQ
Questions
Organization
Translation
Documentation
This box: view · talk · edit

Ó yẹ kí aíje sípò ó ka Ìwé ìléwọ́ ìgbìmọ̀ Wikimedia Foundation kí wọ́n sì ṣe àgbéyẹwò legal and fiduciary obligations for trustees ṣáájú kí wọ́n tó fi ifẹ́ wọn hàn láti kópa.

Iṣẹ́ àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe

Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe ni yóò ma ṣàbójútó àwọn iṣẹ́ ọláọ́kan-ò-jọ̀kan Wikimedia Foundation lágbàáyé. Ṣíṣàwárí àwọn òṣìṣẹ́ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe tí ó peregedé ni yóò jẹ́ kí àwọn iṣẹ́ àjọ Wikimedia ó kẹ́sẹ járí kí ó sì gbòòrò si ní gbogbo àgbáyé. Àmọ́, iṣẹ́ wọn kìí ṣe láti ṣe agbátẹrù fún iṣẹ́ ojoojúmọ́ tí àjọ Wikimedia ń ṣe, bí kò ṣe kí wọ́ ṣe òfin, kí wọ́n má a ṣọ́ ìṣesí iṣẹ́, kí wọ́n sí jẹ́ àwòkọ́ṣe rere.

lára iṣẹ́ wọn náà tún ni:

  • Pípanu pọ̀ gbé ìgbésẹ̀ akin lórí èrò, ìpinu ati àlàkalẹ̀ ètò tó yanrantí;
  • Wíwo ṣàkun ewu tàbí ìpalára tí iṣẹ́ àjọ Wikimedia Foundation lè ní, ṣíṣọ́ ètò ìṣúná àti bí àjọ Wikimedia Foundation yóò ṣe má a tẹ̀lé àwọn òfin ati àlàkalẹ̀ ètò.
  • Gbígba Aláṣẹ àgbà (CEO) àti àwọn òṣìṣẹ́ àgbà nímọ̀ràn láti ma ṣamúlò ìmọ̀ àti ìrírí wọn lẹ́nu iwṣẹ́.
  • Bíbá gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ Wikimedia sọ̀rọ̀ lórí iṣẹ́ àti ipa ìgbìmọ̀ náà láwùjọ wọn.

Àwọn ìgbìmọ̀ ni wọ́n yóò ma ṣàmójútó òfin àti ìlànà àjọ Wikimedia. Àwọn náà ni wọ́n tún lè gba oríṣiríṣi ẹ̀yà ènìyàn tí wọ́n irúfẹ́ ìmọ̀ tí wọ́n wá wọlé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́. Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe yí gbọ́dọ̀ ma ti àjọ Wikimedia Foundation lẹ́yìn ni; wọn kò gbodọ̀ tì wọ́n lójú. Ìgbìmọ̀ yí lè yan awon ọmọ ẹgbẹ́ wọn láàrín ara wọn pẹ̀lú kí wọ́n dìbò àmọ́ oníṣẹ́ kan tí ó bá ti di ọmọ ìgbìmọ̀ yí kò ní ànfaní láti tún ṣojú àwùjọ rẹ̀ mọ́ lásìkò tí ó ṣe wà nínú ìgbìmọ̀ náà.

Ẹ lè ka siwájú si nípa ìṣeẹ́ ati ipa ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe yí ní Wikimedia Foundation Board Handbook.

Ohun àmúyẹ fún adíje

Olùdíje gbọ́dọ̀ ṣe àmúlò gbogbo ìṣẹ́ tí wọ́n bá gbé le lọ́wọ́. Lára àwọn iṣẹ́ náà ni kí ó ṣe ọ̀fín-tótó sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó bá yẹ, kí ó gbé ìgbésẹ̀ akin lórí ìṣẹ̀lẹ̀, kí ó sì kópa nínú ìpàdé ìgbìmọ̀. Olùdíje lè ka nípa ohun amúyẹ yí siwájú si ní: gẹ́gẹ́ bí òndìbò.

  • Òndíje kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n tàbí arúfin pàá pàá jùlọ nípa ìwà àìlóòtọ́ ati ẹ̀tàn;
  • Òndíje kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí wọ́n yọ kúrò nípò aṣojú ilé-iṣẹ́ yálà ti ìjọba tàbí ti aládàáni látàrí ìwà àjẹbánu;
  • Ní àsìkò ìyàn sípò yí, orúkọ oníṣẹ́ òndíje tàbí olùdìbò kò gbọdọ wà ní fí fagilé;
  • Bí o bá ní ohun àmúyẹ gẹ́gẹ́ bí òndìbò, àtúnṣe akọ́kọ́ òndìbò tàbí olùdíje gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wáyé ní ṣáájú ọjọ́ Kẹsàn án oṣù Kẹfà ọdún 2019;
  • Òndíje gbọ́dọ̀ sọ orúkọ rẹ gan gan nígbà tí ó bá forúkọ sílẹ̀;

A kò fàyè gba kí Òndíje ó lo orúkọ àyídá-yidà nítorí gbogbo akọsílẹ̀ àwọn ìgbìmọ̀ pátá ni ó wà ní ìwò àwùjọ.

  • Òndìbò gbọ́dọ̀ jẹ́ ọmọ ọdún Méjìdínlógún sókè níbaámu pẹ̀lú òfin orílẹ̀-èdè rẹ̀;
  • Òndíje gbọ́dọ̀ fi ìwé ẹ̀rí ọjọ́ orí rẹ sílẹ̀ fún àjọ Wikimedia;

Fíforúkọ sílẹ̀

  1. Nínú Ìforúkọsílẹ̀ rẹ, o lè má fi àwọn àtìlẹyìn tí o bá ti ri gbà hàn lójú ewé Ìforúkọsílẹ̀ náà, bákan náà, o lè má díje pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ ra tó kú nípa lílo slate.
  1. A gba Ìforúkọsílẹ̀ sílẹ̀ láti 00:00 9 2021 (UTC) ati 23:59 29 June 2021 (UTC). Ẹ̀mẹta péré ni o lè ṣe àyípadà sí Ìforúkọsílẹ̀ lẹ́yìn tí o ti forúkọ sílẹ̀, tàbí 23:59 29 June 2021 (UTC). Ṣíṣàtúnṣe ránpẹ́, tàbí ṣíṣàtúnṣe ògbufọ̀ ni a fi àyè gbà láàrín àsìkò yí. (O lè wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa àtúnṣe).
  1. O gbọ́dọ fi ohi ohun àmì ìdánimọ̀ ra sílẹ̀ fún ayẹ̀wò Wikimedia Foundation ṣáájú 23:59 29 June 2021 (UTC). Lẹ́yìn tí o bá forúkọ sílẹ̀ tán, ìkan lára àwọn ìgbìmọ̀ elétò ìdìbò yóò kàn sí ọ lẹ́yìn èyí.

Òndíje tí ó bá kùnà láti tẹ̀lé àwọn ìlànà àti àlàkalẹ̀ wọ̀nyí ni a ó fagilé

Fi àmì ìdánimọ̀ ra sílẹ̀ fún àjọ Wikimedia

Àwọn òndíje tí wọ́n bá fẹ́ díje gbọ́dọ fi ohun ìdánimọ̀ ati ọjọ́ orí wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ayẹ̀wò. Lára àwọn wọn ni:

  • Ìwé àṣẹ ìwakọ̀
  • Ìwé ìrìnà òfurufú
  • Ohun ìdánimọ̀ míràn tí ó fi ọjọ́ orí ra hàn.

Àwọn ohun ìdánimọ̀ yí ni ẹ lè fi ṣọwọ́ sí àjọ Wikimedia ní orí e meèlì lórí secure-info wikimedia.org

Bí o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ṣe àṣàyàn wọn, àjọ Wikimedia lè béèrè àwọn ohun ìdámọ̀ míràn láti lè fi ṣe ìwádí nípa ra siwájú si ṣáájú kí wọ́n tó yan ọ́ sípò ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe.

Bí o ṣe lè forúkọ sílẹ̀

O lè Forúkọ sílẹ̀ láti díje